Romans 3:9-19

Kò sí olóòtítọ́ kan

9 aǸjẹ́ kí ha ni? Àwa ha sàn ju wọn lọ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá: nítorí a fihàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀; 10 bGẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan
11Kò sí ẹni tí òye yé,
kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.
12Gbogbo wọn ni ó ti yapa,
wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè;
kò sí ẹni tí ń ṣe rere,
kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”
13 c“Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn:
ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.”
“Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”
14 d“Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”
15 e“Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀:
16ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.
17Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀:”
18 f“Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”
19 gÀwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.
Copyright information for YorBMYO